1 Àwọn àgbààgbà ẹ̀yà Éfúráímù sì bínú gidigidi sí Gídíónì wọ́n bi í léèrè pé, kí ló dé tí o fi ṣe irú èyí sí wa? Èéṣe tí ìwọ kò fi pè wá nígbà tí ìwọ kọ́kọ́ jáde lọ láti bá àwọn ará Mídíánì jagun? Ohùn ìbínú ni wọ́n fi bá a sọ̀rọ̀.
2 Ṣùgbọ́n Gídíónì dá wọn lóhùn pé, “Àṣeyọrí wo ni mo ti ṣe tí ó tó fi wé tiyín? Àṣàkù àjàrà Éfúráímù kò ha dára ju gbogbo ìkórè àjàrà Ábíésérì lọ bí?
3 Ọlọ́run ti fi Órébù àti Ṣéébù àwọn olórí àwọn ará Mídíánì lé yín lọ́wọ́. Kí ni ohun tí Móṣè ṣe tí ó tó fi wé e yín tàbí tí ó tó àṣeyọrí i yín.” Nígbà tí ó wí èyí ríru ìbínú wọn rọ lẹ̀.
4 Gídíónì àti àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ tẹ̀ṣíwájú láti lépa àwọn ọ̀ta bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ wọ́n, wọ́n dé Jọ́dánì wọ́n sì kọjá sí òdì kejì.
5 Ó wí fún àwọn ọkùnrin Ṣúkótì pé, “Ẹ fún àwọn ọmọ ogun mi ní oúnjẹ diẹ̀, nítorí ó ti rẹ̀ wọ́n, èmi sì ń lépa Ṣébà àti Ṣálímúnà àwọn ọba Mídíánì.”
6 Ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè Ṣúkótì fèsì pé ṣé ọwọ́ rẹ ti tẹ Ṣébà àti Ṣálímúnà náà ni? Èéṣe tí àwa yóò ṣe fún àwọn ológun rẹ ní oúnjẹ?