Onídájọ́ 8:20-26 BMY

20 Ó yí padà sí Jétérì, ọmọ rẹ̀ tí ó dàgbà jùlọ, ó wí fún un pé, “Pa wọ́n!” Ṣùgbọ́n Jétérì kò fa idà rẹ̀ yọ láti pa wọ́n nítorí ó jẹ́ ọ̀dọ́mọdé ẹ̀rù sì bà á láti pa wọ́n.

21 Ṣébà àti Ṣálímúnà dá Gídíónì lóhùn pé, “Wá pa wá fún raàrẹ, ‘Nítorí bí ènìyàn bá ti rí bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ yóò rí.’ ” Gídíónì bọ́ ṣíwájú ó sì pa wọ́n, ó sì mú ohun ọ̀sọ́ tí ó wà ní ọrùn àwọn ràkúnmí wọn.

22 Àwọn ará Ísírẹ́lì wí fún Gídíónì pé, “Jọba lórí wa—ìwọ, àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ-ọmọ rẹ pẹ̀lú, nítorí tí ìwọ ti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Mídíánì.”

23 Ṣùgbọ́n Gídíónì dá wọn lóhùn pé, “Èmi kì yóò jọba lórí yín, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ mi kì yóò jọba lórí yín. Olúwa ni yóò jọba lórí yín.”

24 Ó sì wí pé, “Mo ní ẹ̀bẹ̀ kan tí mo fẹ́ bẹ̀ yín kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín fún mi ní yẹtí kọ̀ọ̀kan láti inú ohun ti ọkàn yín láti inú ìkógun.” (Àṣà àwọn ará Ísímáílì ni láti máa fi yẹtí wúrà sétí.)

25 Wọ́n dáhùn pé, “Tayọ̀-tayọ̀ ni àwa yóò fi wọ́n sílẹ̀.” Wọ́n tẹ́ aṣọ kan sílẹ̀ ọkùnrin kọ̀ọ̀kan sì ń sọ yẹtí kọ̀ọ̀kan tí ó kàn wọ́n láti ibi ìkógun ṣíbẹ̀.

26 Ìwọ̀n òrùka wúrà tí ó bèèrè fún tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán, ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn ún méje (1700) ìwọ̀n ṣékélì èyí tó kìlógírámù mọ́kàndínlógún ààbọ̀ (19.5 kilogram), láìka àwọn ohun ọ̀ṣọ́ àti ohun sísorọ̀ tí ó wà lára ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn àti aṣọ eléṣé àlùkò tí àwọn ọba Mídíánì ń wọ̀ tàbí àwọn ìlẹ̀kẹ̀ tí ó wà ní ọrùn àwọn ràkúnmí wọn.