1 Àwọn àpósítélì àti àwọn arákùnrin ti ó wà ni Jùdíà sì gbọ́ pé àwọn aláìkọlà pẹ̀lú ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
2 Nígbà tí Pétérù sì gòkè wá sí Jerúsálémù, àwọn ti ìkọlá ń bá a wíjọ́
3 wí pé, “Ìwọ wọlé tọ àwọn ènìyàn aláìkọlà lọ, ó sì bá wọn jẹun.”
4 Ṣùgbọ́n Pétérù bẹ̀rẹ̀ sí i là á yé wọn lẹ́sẹẹsẹ, wí pé,
5 “Èmi wà ni ìlú Jópà, mo ń gbàdúrà, mo rí ìran kan lójúran. Ohun èlò kan sọ̀kalẹ̀ bí ewé tákàdá ńlá, tí a ti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá; ó sì wá títí de ọ̀dọ̀ mi.
6 Mo tẹjúmọ́ ọn, mo sì fiyèsí i, mo sí rí ẹran ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin, àti ẹranko ìgbẹ́, àti ohun tí ń rákò, àti ẹyẹ ojú ọ̀run.