33 Èyí ni Ọlọ́run ti mú ṣẹ fún àwa ọmọ wọn, nípa gbígbé Jésù dìde: Bí a sì ti kọwé rẹ̀ nínú Sáàmù kejì pé:“ ‘Ìwọ ni Ọmọ mi;lónìí ni mo bí ọ.’
34 Àti ni tí pé Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí kì yóò tún padà sí ìbàjẹ́ mọ́, ó wí báyí pé:“ ‘Èmi ó fún yín ní ọ̀rẹ́ mímọ́ Dáfídì, tí ó dájú.’
35 Nítorí ó sì wí nínú Sáàmù mìíràn pẹ̀lú pé:“ ‘Ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.’
36 “Nítorí lẹ́yìn ìgbà ti Dáfídì ti sin ìran rẹ tan nípa Ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sùn, a sì tẹ́ ẹ ti àwọn baba rẹ̀, ara rẹ̀ sì rí ìdíbàjẹ́.
37 Ṣùgbọ́n ẹni tí Ọlọ́run jí dìde kò rí ìdíbàjẹ́
38 “Ǹjẹ́ kí ó yé yín, ará pé nípasẹ̀ Jésù yìí ni a ń wàásù ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún yín.
39 Nípa rẹ̀ ni a ń dá olúkúlùkù ẹni tí ó gbàgbọ́ láre kúrò nínú ohun gbogbo, tí a kò lè dá yín láre rẹ̀ nínú òfin Mósè.