39 Nípa rẹ̀ ni a ń dá olúkúlùkù ẹni tí ó gbàgbọ́ láre kúrò nínú ohun gbogbo, tí a kò lè dá yín láre rẹ̀ nínú òfin Mósè.
40 Nítorí náà, ẹ kíyèsára, kí èyí tí a ti sọ nínú ìwé àwọn wòlíì má ṣe dé bá yín pé:
41 “ ‘Ẹ wò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn,kí ẹnu sì yà yín, kí a sì fẹ́ yín kù;nítorí èmi ń ṣe iṣẹ́ kan lọ́jọ́ yín,iṣẹ́ tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́bí ẹnìkan tilẹ̀ ròyìn rẹ̀ fún yín.’ ”
42 Bí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà sì ti ń jáde láti inú sínàgọ́gù, wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé kí a sọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí i fún wọn lọ́jọ́ ìsinmi tí ń bọ̀.
43 Nígbà tí wọn sì jáde nínú sínágọ́gù, ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù àti nínú àwọn olùfọkànsìn aláwọ̀ṣe Júù tẹ̀le Pọ́ọ̀lù àti Básébà, àwọn ẹni tí ó bá wọn sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì rọ̀ wọ́n láti dúró nínú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.
44 Ní ọjọ́ ìsinmi kejì, gbogbo ìlú sí fẹ́rẹ̀ pejọ́ tan lati gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa.
45 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù rí ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, wọ́n kún fún owú, wọ́n ń sọ̀rọ̀-òdì sí ohun ti Pọ́ọ̀lù ń sọ.