1 Ó sí ṣe, ni Ìkóníónì, Pọ́ọ̀lù àti Bánábà júmọ́ wọ inú sínágọ́gù àwọn Júù lọ, wọ́n sì sọ̀rọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù àti àwọn aláìkọlà gbàgbọ́,
2 Ṣùgbọ́n àwọn aláìgbàgbọ́ Júù rú ọkàn àwọn aláìkọlà sókè, wọ́n sì mú wọn ni ọkàn ìkorò sí àwọn arákùnrin náà.
3 Nítorí náà Pọ́ọ̀lù àti Bánábà gbé ibẹ̀ pẹ́, wọ́n ń fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nínú Olúwa, ẹni tí ó jẹ̀rìí sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, ó sì yọ̀ǹda kí iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu máa ti ọwọ́ wọn ṣe.
4 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ìlú náà pín sí méjì: apákan dàpọ̀ mọ́ àwọn Júù, apákan pẹ̀lú àwọn àpósítélì.