4 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ìlú náà pín sí méjì: apákan dàpọ̀ mọ́ àwọn Júù, apákan pẹ̀lú àwọn àpósítélì.
5 Bí àwọn aláìkọlà, àti àwọn Júù pẹ̀lú àwọn olórí wọn ti fẹ́ kọlù wọ́n láti fi àbùkù kàn wọ́n, àti láti sọ wọ́n ní òkúta,
6 wọ́n gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì sálọ sí Lísírà, àti Dábè, àwọn ìlú Líkáóníà àti sí agbégbé àyíká.
7 Níbẹ̀ ni wọ́n sì ń wàásù ìyìn rere.
8 Ọkùnrin kan sí jókòó ni Lísírà, ẹni tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò mókun, arọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí kò rìn rí.
9 Ọkùnrin yìí gbọ́ bí Pọ́ọ̀lù ti ń sọ̀rọ̀: ẹni, nígbà tí ó tẹjúmọ́ ọn ti ó sì rí i pé, ó ni ìgbàgbọ́ fún ìmúláradá.
10 Ó wí fún un ní ohùn rara pé, “Dìde dúró ṣánsán lórí ẹsẹ̀ rẹ!” Ó sì ń fò sókè, ó sì ń rìn.