1 Ó sì wá sí Dábè àti Lísírà: sí kíyèṣi i, ọmọ-ẹ̀yìn kan wà níbẹ̀, tí a ń pè ní Tìmótíù, ọmọ obìnrin kan tí í ṣe Júù, tí ó gbàgbọ́; ṣùgbọ́n Gíríkì ní baba rẹ̀.
2 Ẹni tí a ròhìn rẹ̀ ní rere lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin tí ó wà ní Lísírà àti Ìkóníónì.
3 Òun ni Pọ́ọ̀lù fẹ́ kí ó bá òun lọ; ó sì mú un, ó sì kọ ọ́ ní ilà, nítorí àwọn Júù tí ó wà ní agbégbé wọ̀nyí: nítorí gbogbo wọn mọ̀ pé, Gíríkì ni baba rẹ̀.
4 Bí wọn sì ti ń la àwọn Ìlú lọ, wọ́n ń fi àwọn àṣẹ, tí a tí pinnu láti ọ̀dọ̀ àwọn àpósítélì àti àwọn alàgbà tí ó wà ní Jerúsálémù, lé wọn lọ́wọ́ láti máa pa wọ́n mọ́.
5 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìjọ sì fẹsẹmúlẹ̀ ní ìgbágbọ́, wọn ṣí ń pọ̀ sí i ní iye lójoojumọ́.