20 Nígbà tí wọ́n sì mú wọn tọ àwọn onídájọ́ lọ, wọ́n wí pé, “Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí tí í ṣe Júù, wọ́n ń yọ ìlú wa lẹ́nu jọjọ;
21 Wọ́n sí n kọ́ni ní àṣà tí kò yẹ fún wa, àwa ẹni tí í ṣe ara Romu, láti gbà àti láti tẹ̀lé.”
22 Ọ̀pọ̀ ènìyàn sí jùmọ̀ dìde sì wọn: àwọn olórí sí fà wọ́n láṣọ ya, wọ́n sí pàṣẹ pé, ki a fí ọ̀gọ̀ lù wọ́n.
23 Nígbà tí wọ́n sì lù wọ́n púpọ̀, wọ́n sọ wọ́n sínú túbú, wọ́n kìlọ̀ fún onítúbú kí ó pa wọ́n mọ́ dáradára:
24 Nígbà tí ó gbọ́ irú ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀, ó sọ̀ wọ́n ṣínú túbú tí inú lọ́hùn, ó sí kan àbà mọ wọ́n lẹ́ṣẹ̀.
25 Ṣùgbọ̀n láàrin ọ̀gànjọ́ Pọ́ọ̀lù àti Ṣílà ń gbàdúrà, wọ́n sì ń kọrin ìyìn si Ọlọ́run: àwọn ara túbú sì ń tẹ́tí sí wọn.
26 Lójijì ilẹ̀ mímì ńlá sì mi, tóbẹ́ẹ̀ tí ìpilẹ̀ ile túbú mì tìtì: lọ́gán, gbogbo ilẹ̀kùn sì sí, ìde gbogbo wọn sì tú ṣílẹ̀.