1 Nígbà tí wọn sì ti kọjá Áḿfípólì àti Apolóníà, wọ́n wá sí Tẹsalóníkà, níbi tí sínágọ́gù àwọn Júù wà:
2 Àti Pọ́ọ̀lù, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó wọlé tọ̀ wọ́n lọ, ni ọjọ́ ìsinmi mẹ́ta ó sì ń bá wọn fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ nínú ìwé-mímọ́.
3 Ó ń túmọ̀, ó sí n fihàn pé, Kíríṣítì kò lè sàìmá jìyà, kí o sì jínde kúrò nínú òkú; àti pé, “Jéṣu yìí ẹni tí èmi ń wàásù fún yin, òun ni Kírísítì náà.”
4 A sì yí nínú wọn lọ́kàn padà, wọ́n sì darapọ̀ mọ́ Pọ́ọ̀lù àti Sílà: bákan náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn obìnrin ọlọ́lá, kì í se díẹ̀.
5 Ṣùgbọ́n àwọn Júù jowú, wọn si fa àwọn jàgídíjàgan nínú àwọn ọmọ ìta ènìyàn mọ́ra, wọ́n gbá ẹgbẹ́ jọ, wọ́n sì ń dá ìlú rú; wọ́n sì kọlu ilé Jásónì, wọ́n ń fẹ́ láti mú wọn jáde tọ àwọn ènìyàn lọ.
6 Nìgbà tí wọn kò sì rí wọn, wọ́n wọ́ Jásónì, àti àwọn arákùnrin kan tọ àwọn olórí ìlú lọ, wọ́n ń kígbe pé, “Àwọn wọ̀nyí tí o tí dorí ayé kodò wá sí ìhínyìí pẹ̀lú.