23 Ní àkókò náà ìrúkèrúdò díẹ̀ kan wà nítorí ọ̀nà náà.
24 Nítorí ọkùnrin kan tí a ń pè ní Démétíríù, alágbẹ̀dẹ fàdákà, tí o máa ń fi fàdákà ṣe ilé-òrìṣà fún Dáyánà, ó mú ère tí kò mọ níwọ̀n wá fún àwọn oníṣọ̀nà;
25 Nígbà tí ó pè wọ́n jọ, àti irú àwọn oníṣẹ́-ọ̀nà bẹ́ẹ̀, ó ní, “Alàgbà, ẹ̀yin mọ̀ pé nipa iṣẹ́-ọnà yìí ni àwa fi ní ọrọ̀ wa.
26 Ẹ̀yin sì rí i, ẹ sì gbọ́ pé, kì í ṣe ni Éfésù nìkanṣoṣo ni, ṣùgbọ́n ó fẹrẹ jẹ́ gbogbo Éṣíà, ni Pọ́ọ̀lù yìí ń yí ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́kàn padà, tí ó sì ń dárí wọn wí pé, ohun tí a fi ọwọ́ ṣe, kì í ṣe Ọlọ́run.
27 Kì í sì ṣe pé kìkí iṣẹ́-ọnà wa yìí ni ó wà nínú ewu dídí aṣán; ṣùgbọ́n ilé Dáyánà òrìṣà ńlá yóò di gígàn pẹ̀lú, àti gbogbo ọlá-ńlá rẹ̀ yóò sì run, ẹni tí gbogbo Éṣíà àti gbogbo ayé ń bọ.”
28 Nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n kún fún ìbínú, wọ́n kígbe, wí pé, “Òrìṣà ńlá ni Dáyánà ti ará Éfésù!”
29 Gbogbo ìlú náà sì kún fún ìrúkèrúdò: wọ́n sì fi ipa fa Gáíù àti Árísítaríkù ara Makedóníà lọ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́gbẹ́ Pọ́ọ̀lù nínú ìrìn-àjò.