10 Fírígíà, àti Pàḿfílíà, Íjíbítì, àti agbégbé Líbíà níhà Kírénè; àti àwọn àtìpó Róòmù, àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe Júù.
11 (àti àwọn Júù àti àwọn tí a tipa ẹ̀sìn sọ di Júù); Àwọn ara Kírétè àti Árábíà; àwa gbọ́ tí wọ́n sọ́rọ̀ iṣẹ́ ìyanu ńlá Ọlọ́run ni èdè wa.”
12 Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n aì wá rìrì. Wọn wí fún ara wọn pé, “Kí ni èyí túmọ̀ sí?”
13 Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmìíràn ń sẹ̀fẹ̀, wọn sí wí pé, Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kún fún wáìnì titun.
14 Nígbà náà ni Pétérù díde dúró pẹ̀lú àwọn mọ́kànlá yòókù, ó gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin Júù ènìyàn mi àti gbogbo ẹ̀yin tí ń gbé Jerúsálémù, ẹ jẹ́ kí èyí kí ó yé yin; kí ẹ sì fétísí ọ̀rọ̀ mi.
15 Àwọn wọ̀nyí kò mutí yó, bí ẹ̀yin tí ròó; wákàtí kẹ́ta ọjọ́ sáà ni èyí.
16 Bẹ́ẹ̀ kọ́, èyí ni ọ̀rọ̀ ti a ti sọ láti ẹnu wòlíì Joeli: