37 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, ọkàn wọn gbọgbẹ́, wọn sì wí fún Pétérù àti àwọn àpósítélì yòókù pé, “Ará, kín ni àwa yóò ṣe”
38 Pétérù sì wí fún wọn pé, “Ẹ ronúpìwàdà, kí a sì bamitíìsì olúkúkùkù yín ní orúkọ Jésù Kírísítì fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ yín. Ẹ̀yin yóò sì gba ẹbun Ẹ̀mí Mímọ́
39 Nítorí fún yín ni ìlérí náà, àti fún àwọn ọmọ yín, àti fún gbogbo àwọn tí ó jìnnà réré, àní gbogbo àwọn tí Olúwa Ọlọ́run wa yóò pè.”
40 Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ púpọ̀ mìíràn ni ó fi ń kìlọ̀ tí ó sì ń fi ń rọ̀ wọ́n wí pé, “Ẹ gba ara yín là lọ́wọ́ ìran àrékérekè yìí.”
41 Nítorí náà àwọn tí ó fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ a bamítíìsì wọn, lọ́jọ́ náà a sì kà ìwọn ẹgbẹ̀rùn mẹ́ta ọkàn kún wọn.
42 Wọ́n sì dúró ṣinṣin nínú ẹ̀kọ́ àwọn àpósítélì, àti ní ìdàpọ̀, ní bíbu àkàrà àti nínú àdúrà.
43 Ẹ̀rù sí ba gbogbo ọkàn; iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ àmì púpọ̀ ni a ti ọwọ́ àwọn àpósítélì ṣe.