6 “Bí èmi tí súnmọ́ etí Dámásíkù níwọ̀n ọjọ́kanrí, lójijì ìmọ́lẹ̀ ńlá láti ọ̀run wá mọ́lẹ̀ yí mi ká.
7 Mo sì subú lulẹ̀, mo sì gbọ́ ohùn kan tí ó wí fún mi pé, ‘Ṣọ́ọ̀lù, Ṣọ́ọ̀lù èé ṣe tí ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi?’
8 “Mo sì béèrè pé, ‘Ta ni ìwọ́, Olúwa?’“Ó sì dá mi lóhùn pé, ‘Èmi ni Jésù tí Násárétì, ẹni tí ìwọ́ ń ṣe inúnibíni sí.’
9 Àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú mi rí ìmọ́lẹ̀ náà nítòótọ́, ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ ohùn ẹni tí ń bá mi sọ̀rọ̀.
10 “Mo sí béèrè pé, ‘Kín ni kí èmí kí ó ṣe, Olúwa?’“Olúwa sì wí fún mi pé, ‘Dìde, kí o sì lọ sí Dámásíkù; níbẹ̀ ni a ó sì ti sọ ohun gbogbo fún ọ tí a yàn fún ọ láti ṣe.’
11 Àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú mi fà mí lọ́wọ́ wọ Dámásíkù lọ nítorí tí èmi kò lè ríran nítorí ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ náà ti fọ́ mi ní ojú.
12 “Ọkùnrin kan tí a ń pè ní Ananáyà tọ̀ mí wá, ẹni tó jẹ́ olùfọkànṣìn ti òfin, tí ó sì lórúkọ rere lọ́dọ̀ gbogbo àwọn Júù tí ó ń gbé ibẹ̀.