1 Pọ́ọ̀lù tẹjúmọ́ ìgbìmọ̀, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi tí ń fi gbogbo ẹ̀rí ọkàn rere lo ayé mi níwájú Ọlọ́run títí fí di òní yìí.”
2 Nígbà yìí ni Ananíyà olórí àlùfáà pàṣẹ fún àwọn tí ó dúró tí Pọ́ọ̀lù pé, kí wọn ó gbá a lẹ́nu.
3 Nígbà náà ni Pọ́ọ̀lù wí fún un pé, “Ọlọ́run yóò lù ọ́, ìwọ ogiri tí a kùn lẹ́fun: ìwọ jókòó láti dá mi lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin, ṣùgbọ́n ìwọ gan-an alára rú òfin nípa pípaṣẹ pé kí a lù mí!”
4 Àwọn tí ó dúró tì Pọ́ọ̀lù sì wí pé, “Ìwọ́ ń gan olórí àlùfáà Ọlọ́run?”
5 Pọ́ọ̀lù sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi kò mọ̀ pé olórí àlùfáà ni: nítorí a tí kọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ olórí àwọn ènìyàn rẹ̀ ní búburú.’ ”
6 Ṣùgbọ́n nígbà tí Pọ́ọ̀lù sàkíyèsí pé, apákan wọn jẹ́ Sádúsì, apákan sì jẹ́ Farisí, ó kígbe ní ìgbìmọ̀ pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, Èmi jẹ́ Farisí, ọmọ Farisí sì ni èmi: mo dúró ní ìdájọ́ nítorí ìrètí mi nínú àjíǹde òkú.”
7 Nígbà tí ó sì tí wí èyí, ìyapa dé láàrin àwọn Farisí àti àwọn Sádúsì: àjọ sì pín sì méjì.