11 Ìwọ pẹ̀lú sì ní òye rẹ̀ pé, ìjejìlá ni mo lọ sí Jerúsálémù láti lọ jọ́sìn.
12 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn olùfisùn mi kò rí mi kí ń máa bá ẹnìkẹ́ni jiyàn nínú téḿpílì, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ru àwọn ènìyàn sókè nínú ṣínágọ́gù tàbí ní ibikíbi nínú ìlú:
13 Bẹ́ẹ̀ ní wọ́n kò lè fi ìdí ẹ̀sùn múlẹ̀ níwájú rẹ, èyí tí wọn fi mí sùn sí nísinsìn yìí.
14 Ṣùgbọ́n, èmí jẹ́wọ́ fún ọ pé, èmi ń sin Ọlọ́run àwọn baba wa gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń tẹ̀le ọ̀nà tí wọ́n ń pè ni ìyapa-ìsìn. Èmi ń gbá gbogbo nǹkan ti a kọ sínú ìwé òfin gbọ́, àti tí a kọ sínú ìwé àwọn wòlíì,
15 mo sí ní ìrètí kan náà nínú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí àwọn tìkaráwọn jẹ́wọ́ pẹ̀lú, wí pé àjíǹde òkú ń bọ̀, àti tí olóòtọ́, àti tí aláìsòótọ́.
16 Nínú èyí ni èmi sì ti ń gbìyànjú láti ní ẹ̀rí-ọkàn tí kò lẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run, àti sí ènìyàn nígbà gbogbo.
17 “Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọdun púpọ̀, mo wá sí Jerúsálẹ́mù láti mu ẹ̀bún wá fún àwọn ẹ̀nìyàn mi fún aláìní àti láti fi ọrẹ lélẹ̀.