14 Ṣùgbọ́n, èmí jẹ́wọ́ fún ọ pé, èmi ń sin Ọlọ́run àwọn baba wa gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń tẹ̀le ọ̀nà tí wọ́n ń pè ni ìyapa-ìsìn. Èmi ń gbá gbogbo nǹkan ti a kọ sínú ìwé òfin gbọ́, àti tí a kọ sínú ìwé àwọn wòlíì,
15 mo sí ní ìrètí kan náà nínú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí àwọn tìkaráwọn jẹ́wọ́ pẹ̀lú, wí pé àjíǹde òkú ń bọ̀, àti tí olóòtọ́, àti tí aláìsòótọ́.
16 Nínú èyí ni èmi sì ti ń gbìyànjú láti ní ẹ̀rí-ọkàn tí kò lẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run, àti sí ènìyàn nígbà gbogbo.
17 “Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọdun púpọ̀, mo wá sí Jerúsálẹ́mù láti mu ẹ̀bún wá fún àwọn ẹ̀nìyàn mi fún aláìní àti láti fi ọrẹ lélẹ̀.
18 Nínú ṣíṣe nǹkan wọ̀nyí, wọ́n rí mí nínú iyẹ̀wù tẹ́ḿpílì, bí mo ti ń parí ètò ìwẹ́nú, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ní àárin àwùjọ ènìyàn, tàbí pẹ̀lú ariwo.
19 Ṣùgbọ́n àwọn Júù kan láti ẹkùn Éṣíà wà níbẹ̀, àwọn tí ì bá wà níhìn-ín yìí níwájú rẹ, kí wọn já mi nírọ́, bí wọ́n bá ní ohunkohun sí mi.
20 Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí tíkarawọn sọ iṣẹ́ búburú tí wọ́n rí lọ́wọ́ mi, nígbà tí mo dúró níwájú àjọ ìgbìmọ̀.