19 Ṣùgbọ́n àwọn Júù kan láti ẹkùn Éṣíà wà níbẹ̀, àwọn tí ì bá wà níhìn-ín yìí níwájú rẹ, kí wọn já mi nírọ́, bí wọ́n bá ní ohunkohun sí mi.
20 Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí tíkarawọn sọ iṣẹ́ búburú tí wọ́n rí lọ́wọ́ mi, nígbà tí mo dúró níwájú àjọ ìgbìmọ̀.
21 Bí kò ṣe tí gbolóhùn kan yìí, tí mo kégbe rẹ̀ ṣíta nígbà tí mo dúró láàrin wọn: ‘Èyí ni tìtorí àjíǹde òkú ni a ṣe ba mi wíjọ́ lọ́dọ̀ yín lóni yìí!’ ”
22 Nígbà tí Fẹ́líkísì gbọ́ nǹkan wọ̀nyí òye sà yè e ní àyétan nípa ọ̀nà náà; ó tú wọn ká ná, ó ní, “Nígbà tí Lísíà olórí ogun bá ṣọ̀kalẹ̀ wá, èmi ó wádìí ọ̀ràn yín dájú.”
23 Ó sì pàṣẹ fún balógun ọ̀run kan kí ó fi Pọ́ọ̀lù sí a bẹ́ ìsọ́, ṣùgbọ́n kí ó fún un ní ààyè, àti pé kí ó má ṣe dá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lẹ́kùn láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún un.
24 Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan Fẹ́líkísì pẹ̀lú Dírúsílà ìyàwó rẹ̀ dé, obìrin tí í ṣe Júù. Ó ranṣẹ́ pé Pọ́ọ̀lù, ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀ nípa ìgbàgbọ́ nínú Kírísítì Jésù.
25 Bí Pọ́ọ̀lù sì tí ń sọ àsọyé nípa tí òdodo àti àìrékọjá àti ìdájọ́ tí ń bọ̀, ẹ̀rù ba Fẹ́líkísì, ó dáhùn wí pé, “Èyí tí o sọ nì tó ná! Máa lọ nísinsìn yìí ná. Nígbà tí mo bá sì ní àkókò tí ó wọ̀, èmi ó ránṣẹ́ pè ọ́.”