2 Nígbà tí a sí tí pè Pọ́ọ̀lù jáde, Tátúlù gbé ẹjọ́ rẹ̀ kalẹ̀ níwájú Fẹ́líkísì ó wí pé: “Àwa ti wà ní àlàáfíà ní abẹ́ ìjọba rẹ lá ìgbà pípẹ́ wá, àti pé ìfojúsù rẹ ti mú àyípadà rere bá orílẹ̀-èdè yìí.
3 Ní ibi gbogbo àti ní ọ̀nà gbogbo, Fẹ́líkísì ọlọ́lá jùlọ, ní àwa ń tẹ́wọ́gbà á pẹ̀lú ọpẹ́ gbogbo.
4 Ṣùgbọ́n kí èmi má baa dá ọ dúró pẹ́ títí, mo bẹ̀ ọ́ kí o fi ìyọ́nú rẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ díẹ̀ lẹ́nu wa.
5 “Nítorí àwa rí ọkùnrin yìí, ó jẹ́ oníjàngbàn ènìyàn, ẹni tí ó ń dá rúkèrúdò ṣílẹ̀ láàrin gbogbo àwọn Júù tí ó wà ní gbogbo ayé. Òun ni aṣáájú búburú kan nínú ẹ̀yà àwọn Násárénè:
6 Ẹni tí ó gbìyànjú láti ba tẹ́ḿpílì jẹ́: ṣùgbọ́n àwa gbá a mú àwa sí fẹ báa ṣe ẹjọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin wa.
7 Ṣùgbọ́n Lísíà olórí ogun dé, ó fì agbára ńlá gbà á lọ́wọ́ wa:
8 Nígbà tí ìwọ fúnrarẹ bá wádìí ọ̀rọ̀ fínní fínni lẹ́nu rẹ̀, ìwọ ó lè ní òye òtítọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí àwa fi ẹ̀ṣùn rẹ̀ kàn án.”