24 Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan Fẹ́líkísì pẹ̀lú Dírúsílà ìyàwó rẹ̀ dé, obìrin tí í ṣe Júù. Ó ranṣẹ́ pé Pọ́ọ̀lù, ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀ nípa ìgbàgbọ́ nínú Kírísítì Jésù.
25 Bí Pọ́ọ̀lù sì tí ń sọ àsọyé nípa tí òdodo àti àìrékọjá àti ìdájọ́ tí ń bọ̀, ẹ̀rù ba Fẹ́líkísì, ó dáhùn wí pé, “Èyí tí o sọ nì tó ná! Máa lọ nísinsìn yìí ná. Nígbà tí mo bá sì ní àkókò tí ó wọ̀, èmi ó ránṣẹ́ pè ọ́.”
26 Ní àkókó yìí kan náà, ó ń retí pẹ̀lú pé Pọ́ọ̀lù yóò mú owó-ẹ̀yìn wá fún òun, kí òun baà lè dá a sílẹ̀: nítorí náà, a sì máa ránṣẹ́ sì í nígbàkúgbà, a máa bá a sọ̀rọ̀.
27 Lẹ́yìn ọdun méjì, Póríkíúsì Fẹ́sítúsì rọ́pò Fẹ́líkísì: Fẹ́líkísì ṣí ń fẹ́ se ojú rere fún àwọn Júù, ó fí Pọ́ọ̀lù sìlẹ́ nínú túbú.