6 Ẹni tí ó gbìyànjú láti ba tẹ́ḿpílì jẹ́: ṣùgbọ́n àwa gbá a mú àwa sí fẹ báa ṣe ẹjọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin wa.
7 Ṣùgbọ́n Lísíà olórí ogun dé, ó fì agbára ńlá gbà á lọ́wọ́ wa:
8 Nígbà tí ìwọ fúnrarẹ bá wádìí ọ̀rọ̀ fínní fínni lẹ́nu rẹ̀, ìwọ ó lè ní òye òtítọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí àwa fi ẹ̀ṣùn rẹ̀ kàn án.”
9 Àwọn Júù pẹ̀lú sì fi ohùn sí i wí pé, ní òtítọ́ bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí.
10 Nígbà tí baálẹ̀ ṣẹ́wọ́ sì i pé kí ó sọ̀rọ̀, Pọ́ọ̀lù sì dáhùn wí pe: “Bí mo tí mọ̀ pé láti ọdún mélòó yìí wá, ní ìwọ tí ṣe onídájọ́ orílẹ̀-èdè yìí, nítorí náà mo fi tayọ̀ tayọ̀ wí tí ẹnu mi.
11 Ìwọ pẹ̀lú sì ní òye rẹ̀ pé, ìjejìlá ni mo lọ sí Jerúsálémù láti lọ jọ́sìn.
12 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn olùfisùn mi kò rí mi kí ń máa bá ẹnìkẹ́ni jiyàn nínú téḿpílì, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ru àwọn ènìyàn sókè nínú ṣínágọ́gù tàbí ní ibikíbi nínú ìlú: