23 Pé, Kírísítì yóò jìyà, àti pé Òun ni yóò jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láti jíǹde kúrò nínú òkú, Òun ni yóò sí kéde ìmọ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn àti fún àwọn Kèfèrì.”
24 Ní ìkóríta yìí Fẹ́sítúsì kọ dí àwíjàre Pọ́ọ̀lù, ó wí lóhùn rara pé, “Pọ́ọ̀lù, orí rẹ dàrú; ẹ̀kọ́ àkọ́jù rẹ ti dà ọ́ ní orí rú!”
25 Pọ́ọ̀lù da lóhùn wí pé, “Orí mi kò dà rú, Fẹ́sítúsì ọlọ́lá jùlọ; ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ òtítọ́ àti ọ̀rọ̀ òye ni èmi ń sọ jáde.
26 Nítorí ọba mọ̀ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, níwájú ẹni tí èmi ń ṣọ̀rọ̀ ni àìbẹ̀rù: nítorí mo gbàgbọ́ pé ọ̀kan nínú nǹkan wọ̀nyí kò pamọ́ fún un, nítorí tí a kò ṣe nǹkan yìí ní ìkọ̀kọ̀.
27 Àgírípà ọba, ìwọ gba àwọn wòlíì gbọ́ bí? Èmi mọ̀ pé ìwọ gbàgbọ́.”
28 Àgírípà sì wí fún Pọ́ọ̀lù pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ró pé ìwọ́ fi àkókò díẹ̀ yìí sọ mí di Kírísítìẹ́nì?”
29 Pọ́ọ̀lù sì dáhùn wí pé, “Ní àkókò kúkúrú tàbí gígùn: mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kí ó má ṣe ìwọ nìkan, ṣùgbọ́n kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi lónìí pẹ̀lú lè di irú ènìyàn tí èmi jẹ́ láìsí ẹ̀wọ̀n wọ̀nyí.”