1 Ní ọjọ́ kan Pétérù àti Jòhánù jùmọ̀ ń gòkè lọ sí tẹ́ḿpìlì ní wákàtí àdúrà; tí í ṣe wákàtí mẹ́ta ọ̀sán.
2 Wọn sì gbé ọkùnrin kan ti ó yarọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí wọ́n máa ń gbé kalẹ̀ lójoojúmọ́ lẹ́nu-ọ̀nà tẹ́ḿpìlì ti a ń pè ni Dáradára, láti máa ṣagbe lọ́wọ́ àwọn tí ń wọ inú tẹ́ḿpìlì lọ,
3 Nígbà tí ó rí Pétérù àti Jòhánù bí wọn tí fẹ́ wọ inú tẹ́ḿpìlì, ó sagbe.
4 Pétérù sì tẹjúmọ́ ọn, pẹ̀lú Jòhánù, ó ní “Wò wá!”