2 Wọn sì gbé ọkùnrin kan ti ó yarọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí wọ́n máa ń gbé kalẹ̀ lójoojúmọ́ lẹ́nu-ọ̀nà tẹ́ḿpìlì ti a ń pè ni Dáradára, láti máa ṣagbe lọ́wọ́ àwọn tí ń wọ inú tẹ́ḿpìlì lọ,
3 Nígbà tí ó rí Pétérù àti Jòhánù bí wọn tí fẹ́ wọ inú tẹ́ḿpìlì, ó sagbe.
4 Pétérù sì tẹjúmọ́ ọn, pẹ̀lú Jòhánù, ó ní “Wò wá!”
5 Ó sì fiyèsí wọn, ó ń réti láti rí nǹkan gbà lọ́wọ́ wọn.
6 Pétérù wí pé, “Góòlù àti fàdákà èmi kò ní, ṣùgbọ́n ohun tí mo ní èyí náà ni mo fifún ọ: Ní orúkọ Jésù Kírísítì ti Násárẹ́tì, dìde kí o sì máa rìn.”
7 Ó sì fà á lọ́wọ́ ọ̀tún, ó sì gbé dìde; lójúkán náà ẹsẹ̀ rẹ̀ àti egungun kókósẹ̀ rẹ̀ sì mókun.
8 Ó sì ń fò sókè, ó dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn, ó sì bá wọn wọ inú tẹ́ḿpìlì lọ, ó ń rìn, ó sì ń fò, ó sì yín Ọlọ́run.