7 Ó sì fà á lọ́wọ́ ọ̀tún, ó sì gbé dìde; lójúkán náà ẹsẹ̀ rẹ̀ àti egungun kókósẹ̀ rẹ̀ sì mókun.
8 Ó sì ń fò sókè, ó dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn, ó sì bá wọn wọ inú tẹ́ḿpìlì lọ, ó ń rìn, ó sì ń fò, ó sì yín Ọlọ́run.
9 Gbogbo ènìyàn sì rí i, ó ń rìn, ó sì yin Ọlọ́run:
10 Wọn sì mọ̀ pé òun ni ó ti jókòó tí ń ṣagbe lẹ́nu ọ̀nà Dáradára ti tẹ́ḿpìlì náà; hà, sì ṣe wọn, ẹnu sì yà wọn gidigidi sí ohun tí ó ṣe lára rẹ̀.
11 Bí arọ ti a mú láradá sì ti di Pétérù àti Jòhánù mú, gbogbo ènìyàn júmọ́ sure tọ̀ wọ́n lọ ni ìloro ti a ń pè ní ti Sólómónì, pẹ̀lú ìyàlẹ́nú ńlá.
12 Nígbà tí Pétérù sì rí i, ó dáhùn, ó wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, è é ṣe tí háà fi ń ṣe yín sí èyí? Tàbí è é ṣe ti ẹ̀yin fi tẹjúmọ́ wa, bí ẹni pé agbára tàbí ìwà mímọ́ wa ni àwa fi ṣe é ti ọkùnrin yìí fi ń rìn?
13 Ọlọ́run Ábúráhámù, àti ti Ísáàkì, àti ti Jákọ́bù, Ọlọ́run àwọn baba wa, òun ni ó ti yin Jésù ìránṣẹ́ rẹ̀ lógo; ẹni tí ẹ̀yin ti fi lé wọn lọ́wọ́, tí ẹ̀yin sì sẹ́ níwájú Pílátù, nígbà tí ó ti pinnu rẹ̀ láti dá a sílẹ̀.