3 Wọn sì náwọ́ mú wọn, wọn sì tì wọ́n mọ́ ilé túbú títí ó fi dí ijọ́ kejì; nítorí tí alẹ́ ti lẹ́ tan.
4 Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà gbàgbọ́; iye àwọn ọkùnrin náà sì tó ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (5000).
5 Ó sì ṣe níjọ kejì, àwọn olórí wọn àti àwọn alàgbà àti àwọn olùkọ́ni ní òfin péjọ sí Jerúsálémù.
6 Àti Ánà olórí àlùfáà, àti Káíáfà, àti Jòhánù, àti Alekisáńdérù, àti iye àwọn tí i ṣe ìbátan olórí àlùfáà.
7 Wọ́n mú Pétérù àti Jòhánù dúró níwájú wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè ìbéèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Nípa agbára tàbí orúkọ wo ni ẹ̀yin fi ṣe èyí?”
8 Nígbà náà ni Pétérù kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin olórí àti ẹ̀yin alàgbà àwọn ènìyàn!
9 Bí ó bá ṣe pé a ń wádìí wa lónì ní tí iṣẹ́ rere ti a ṣe lára abirùn náà, bí a ti ṣe mú ọkùnrin yìí láradá,