32 Ìjọ àwọn tí ó gbàgbọ́ sì wà ní ọkàn kan àti inú kan; kò sì sí ẹnìkan tí ó wí pé ohun kan nínú ohun ìní rẹ̀ jẹ́ ti ara rẹ̀; ṣùgbọ́n gbogbo wọn ní ohun gbogbo ní ìsọ̀kan.
33 Agbára ńlá ni àwọn àpósítélì sì fi ń jẹ́rìí àjíǹde Jésù Olúwa, Oore-ọ̀fẹ́ púpọ̀ sì wà lórí gbogbo wọn.
34 Nítorí kò sí ẹnìkan nínú wọn tí ó ṣe aláìní, nítorí iye àwọn tí ó ní ilẹ̀ tàbí ilé tà wọ́n, wọ́n sì mú owó ohun tí wọn tà wá.
35 Wọ́n sì fi í lélẹ̀ lẹ́ṣẹ̀ àwọn àpósítélì, wọn sì ń pín fún olukúlúkù gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe aláìní sí.
36 Àti Jóṣéfù, tí a ti ọwọ́ àwọn àpósítélì sọ àpèlé rẹ̀ ní Bánábà (ìtúmọ̀ èyí tí ń jẹ Ọmọ-Ìtùnú), ẹ̀yà Léfì, àti ará Sáípúrọ́sì.
37 Ó ní ilẹ̀ kan, ó tà á, ó mú owó rẹ̀ wá, ó sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn àpósítélì.