10 Lójúkan náà ó sì ṣubú lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó sì kú; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì wọlé wọ́n bá a ní òkú, wọ́n sì gbé e jáde, wọ́n sín in lẹ́bá ọkọ rẹ̀.
11 Ẹ̀rù ńlá sì bá gbogbo ìjọ àti gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nǹkan wọ̀nyí.
12 A sì ti ọwọ́ àwọn àpósítélì ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu púpọ̀ láàrin àwọn ènìyàn. Gbogbo wọn sì fi ọkàn kan wà ní ìloro Sólómónì.
13 Kò sí nínú àwọn ìyókù tí ó jẹ́ gbìyànjú láti darapọ̀ mọ́ wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń fi ọ̀wọ̀ gíga fún wọn.
14 Ṣùgbọ́n ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀, a sì ń yan àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin tí ó gba Olúwa gbọ́ kún iye wọn sí i.
15 Tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ń gbé àwọn abirùn jáde sí òpópónà, tí wọn ń tẹ́ wọn sí orí bẹ́ẹ̀dì àti ẹní kí òjìji Pétérù ba à le gba orí ẹlòmíràn nínú wọn bí ó bá ti ń kọjá lọ.
16 Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì kó ara wọn jọ láti àwọn ìlú tí ó yí Jerúsálémù ká, wọn ń mú àwọn abirùn wá àti àwọn tí ara kan fún ẹ̀mí àìmọ́; a sì mu olúkúlùkù wọn ní ara dá.