20 Ó sì wí pé “Ẹ lọ dúró nínú tẹ́ḿpìlì kí ẹ sì máa sọ́ ọ̀rọ̀ ìyè yìí ní ẹ̀kúnrẹ́ré fún àwọn ènìyàn.”
21 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ èyí, wọ́n wọ tẹ́ḿpílì lọ ní kùtùkùtù, wọ́n sì ń kọ́ni.Nígbà tí olórí àlùfáà àti àwọn ti ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ dé, wọn sì pè àpèjọ ìgbìmọ̀, àti gbogbo àwọn àgbààgbà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọn sì ránṣẹ́ sí ilé túbú láti mú àwọn àpósítélì wá.
22 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olùsọ́ dé ibẹ̀ wọn kò sì rí wọn nínú túbú, wọn pàda wá, wọn sí sọ fún wọn pé,
23 “Àwa bá ilé túbú ni títí pinpin, àti àwọn olùsọ́ dúró lóde níwájú ilẹ́kùn; ṣùgbọ́n nígbà tí àwa sí ilẹ̀kùn, àwa kò bá ẹnìkan nínú túbú.”
24 Nígbà tí olórí ẹ̀sọ́ tẹ́ḿpílì àti àwọn olórí àlùfáà sí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n dààmú nítorí wọn kò mọ ibi tí ọ̀rọ̀ yìí yóò yọrí sí.
25 Nígbà náà ni ẹnìkan dé, ó wí fún wọn pé, “Wò ó, àwọn ọkùnrin tí ẹ̀yin fi sínú túbú wà ní tẹ́ḿpílì, wọn dúró wọ́n sì ń kọ́ àwọn ènìyàn.”
26 Nígbà náà ni olórí ẹ̀ṣọ́ lọ pẹ̀lú àwọn olúsọ́, ó sì mú àwọn àpósítélì wá. Wọn kò fi ipá múwọn, nítorí tí wọn bẹ̀rù àwọn ènìyàn kí a má ba à sọ wọ́n ní òkúta.