29 Ṣùgbọ́n Pétérù àti àwọn àpósítélì dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Àwa kò gbọdọ̀ má gbọ́ tí Ọlọ́run ju ti ènìyàn lọ!
30 Ọlọ́run àwọn baba wa jí Jésù dìde kúrò ní ipò òkú, ẹni tí ẹ̀yin pa nípa gbígbé kọ́ sí orí igi.
31 Òun ni Ọlọ́run fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbé gẹ́gẹ́ bí Ọmọ-aladé àti Olùgbàlà láti fi ìrònúpìwàdà àti ìdàríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún Ísírẹ́lì.
32 Àwa sì ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí, àti gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti se ẹlẹ́rìí pẹ̀lú, tí Ọlọ́run fifún àwọn tí ó gbà á gbọ́.”
33 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ọkàn wọn gbọgbẹ́ dé inú, wọ́n gbérò láti pa wọ́n.
34 Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àjọ ìgbìmọ̀, tí a ń pè ni Gàmálíẹ́lì, Farisí àti àmofìn, tí ó ní ìyìn gidigidi lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn, ó dìde dúró, ó ni kí a mú àwọn àpósítélì bì sẹ́yìn díẹ̀.
35 Ó sì wí fún wọn pé “Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, ẹ kíyèsí ara yín lóhun tí ẹ̀yin ń pète láti ṣe sí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí.