8 Pétérù sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Wí fún mi, ṣé iye yìí ni ìwọ àti Ananíyà gbà lórí ilẹ̀?”Ó sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, iye rẹ̀ nìyẹn.”
9 Pétérù sí wí fún un pé, “È é ṣe ti ẹ̀yin fohùn sọ̀kan láti dán Ẹ̀mí Mímọ́ wò? Wò ó, ẹsẹ̀ àwọn tí ó sìnkú ọkọ rẹ ń bẹ lẹ́nu ọ̀nà, wọn ó sì gbe ìwọ náà jáde.”
10 Lójúkan náà ó sì ṣubú lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó sì kú; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì wọlé wọ́n bá a ní òkú, wọ́n sì gbé e jáde, wọ́n sín in lẹ́bá ọkọ rẹ̀.
11 Ẹ̀rù ńlá sì bá gbogbo ìjọ àti gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nǹkan wọ̀nyí.
12 A sì ti ọwọ́ àwọn àpósítélì ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu púpọ̀ láàrin àwọn ènìyàn. Gbogbo wọn sì fi ọkàn kan wà ní ìloro Sólómónì.
13 Kò sí nínú àwọn ìyókù tí ó jẹ́ gbìyànjú láti darapọ̀ mọ́ wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń fi ọ̀wọ̀ gíga fún wọn.
14 Ṣùgbọ́n ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀, a sì ń yan àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin tí ó gba Olúwa gbọ́ kún iye wọn sí i.