19 Òun náà ni ó ṣe àrékekè sí àwọn ìbátan wa. Wọn sì hùwà búburú sí àwọn baba wa, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi já àwọn ọmọ-ọwọ́ wọn kúrò lọ́wọ́ wọn nítorí kí wọn má ṣe yè.
20 “Ní àkókò náà ni a bí Mósè, ẹni tí ó lẹ́wà púpọ̀, tí wọn sí bọ́ lóṣù mẹ́ta ni ilé baba rẹ̀.
21 Nígbà tí wọn sí gbe é sọnù, ọmọbìnrin Fáráò gbé e, ó sì tọ ọ́ dàgbà gẹ́gẹ́ bí ọmọ ara rẹ̀.
22 A sì kọ́ Mósè ni gbogbo ọgbọ́n ara Íjíbítì, ó sì pọ̀ ni ọ̀rọ̀ àti ní ìṣe.
23 “Nígbà tí Mósè di ọmọ ogójì ọdún, ó sọ sí i lọ́kàn láti lọ bẹ àwọn ọmọ Isríẹ́lì ará rẹ̀ wò.
24 Nígbà tí ó sì rí ọ̀kan nínú wọ́n tí ara Éjíbítì kan ń jẹ́ ní ìyà, ó gbéjà rẹ̀, ó gbẹ̀sàn ẹni tí wọ́n jẹ ní ìyà nípa lílu ara Íjíbítì náà pa:
25 Mósè rò bí àwọn ará òun mọ̀ pé Ọlọ́run yóò ti ọwọ́ òun gbà wọn; ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀.