24 Nígbà tí ó sì rí ọ̀kan nínú wọ́n tí ara Éjíbítì kan ń jẹ́ ní ìyà, ó gbéjà rẹ̀, ó gbẹ̀sàn ẹni tí wọ́n jẹ ní ìyà nípa lílu ara Íjíbítì náà pa:
25 Mósè rò bí àwọn ará òun mọ̀ pé Ọlọ́run yóò ti ọwọ́ òun gbà wọn; ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀.
26 Ní ọjọ́ kejì Mósè yọ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì méjì bí wọ́n ti ń jà. Òun ì bá sí parí rẹ̀ fún wọn. Ó wí pé, ‘Ènìyàn mi, ará ni ẹ̀yin; è é ṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣe ohun tí kò tọ́ sí ara yín?’
27 “Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fínràn sí ẹnìkejì rẹ̀ tì Mósè sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó wí pé, ‘Ta ni ó fi ọ jẹ olórí àti onídàjọ́ wa?
28 Àbí ìwọ ń fẹ́ pa mi gẹ́gẹ́ bí o ti pa ará Íjíbítì lánàá?’
29 Mósè sì sá nítorí ọ̀rọ̀ yìí, ó sì wa ṣe àtìpó ni ilẹ̀ Mídíànì, níbi tí ó gbé bí ọmọ méjì.
30 “Nígbà tí ogójì ọdún sì pé, ańgẹ́lì Olúwa fara hàn Mósè ní ijù, ní òkè Sínáì, nínú ọ̀wọ́ iná ìgbẹ́.