3 Ọlọ́run fún un pé, ‘Jáde kúrò ni orílẹ̀-èdè rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, kí ó sì lọ sí ilẹ̀ tí èmi yóò fi hàn ọ́.’
4 “Nígbà náà ni ó jáde kúrò ní ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà, ó sì ṣe àtipó ni Háránì. Lẹ́yìn ìgbà tí baba rẹ̀ sì kú, Ọlọ́run mú un sípò padà wá sí ilẹ̀ yìí, níbi tí ẹ̀yin ń gbé báyìí.
5 Kò sí fún un ni ìní kan, àní tó bi ìwọ̀n ààyè ẹṣẹ̀ kan. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run se ìlérí fún pé, òun yóò fi ilẹ̀-ìní náà fún un àti fún àwọn irú ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, nígbà tí kò tí ì ní ọmọ.
6 Ọlọ́run sì sọ báyìí pé: ‘Irú-ọmọ rẹ̀ yóò ṣe àtìpó ni ilẹ̀ àjèjì; wọn ó sì sọ wọn di ẹrú, wọn ó sì pọ́n wọn lójú ni irínwó ọdún.’
7 Ọlọ́run wí pé, ‘Orílẹ̀-èdè náà tí wọn ó ṣe ẹrú fún ni èmi ó dá lẹ́jọ́; lẹ́yìn náà ni wọn ó sì wá sìn mí níhín yìí.’
8 Ó sì fún Ábúráhámù ni májẹ̀mú ìkọlà. Ábúráhámù bí Ísáákì, ó kọ ọ́ ní ilà-abẹ́ ni ijọ́ kẹjọ tí ó bí i. Ísáákì sí bí Jákọ́bù, Jákọ́bù sì bí àwọn baba ńlá méjìlá.
9 “Àwọn baba ńlá sí ṣe ìlara Jósẹ́fù, wọ́n sì tà á sí Íjíbítì; ṣùgbọ́n Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀,