48 “Ṣùgbọ́n Ọ̀gá-ògo kì í gbé ilé ti a fi ọwọ́ kọ́: gẹ́gẹ́ bí wòlíì ti wí pé:
49 “ ‘Ọ̀run ni ìtẹ́ mi,ayé ni àpòtí ìtìsẹ̀ mi.Irú ilé kínní ẹ̀yin yóò kọ́ fún mi?ni Olúwa wí.Tàbí níbo ni yóò jẹ́ ibi isinmi mi?
50 Ọwọ́ mi kò ha ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.’
51 “Ẹ̀yin ọlọ́rùn-líle àti aláìkọlà àyà àti etí! Bí àwọn baba yín gẹ́lẹ́ ni ẹ̀yín rí: Nígbà gbogbo ni ẹ̀yin máa ń dènà Ẹ̀mí Mímọ́!
52 Ǹjẹ́ ó tilẹ̀ wà nínú àwọn wòlíì tí àwọn baba yín kò ṣe inúnibíni sí? Wọn sì ti pa àwọn ti ó ti ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wíwá Ẹni Olódodo náà. Nísinsin yìí ẹ̀yin ti dalẹ̀ rẹ̀ ẹ̀yin sí ti pa.
53 Ẹ̀yin tí ó gba òfin, gẹ́gẹ́ bí àwọn ańgẹ́lì ti fi fún ni, tí ẹ kò sí pa á mọ́.”
54 Nígbà tí wọn sì gbọ́ nǹkan wọ̀nyí ọkàn wọn gbọgbẹ́ dé inú, wọn sì payín keke sí i.