7 Ọlọ́run wí pé, ‘Orílẹ̀-èdè náà tí wọn ó ṣe ẹrú fún ni èmi ó dá lẹ́jọ́; lẹ́yìn náà ni wọn ó sì wá sìn mí níhín yìí.’
8 Ó sì fún Ábúráhámù ni májẹ̀mú ìkọlà. Ábúráhámù bí Ísáákì, ó kọ ọ́ ní ilà-abẹ́ ni ijọ́ kẹjọ tí ó bí i. Ísáákì sí bí Jákọ́bù, Jákọ́bù sì bí àwọn baba ńlá méjìlá.
9 “Àwọn baba ńlá sí ṣe ìlara Jósẹ́fù, wọ́n sì tà á sí Íjíbítì; ṣùgbọ́n Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀,
10 ó sì yọ ọ́ kúrò nínú ìpọ́njú rẹ̀ gbogbo. Ó sì fún Jósẹ́fù ní ọgbọ́n, ó sì mú kí ó rí ojúrere Fáráò ọba Íjíbítì; òun sì fi jẹ baálẹ̀ Íjíbítì àti gbogbo ilé rẹ̀.
11 “Ìyàn kan sì mú ni gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì àti ni Kénánì, àti ìpọ́njú ńlá, àwọn baba wa kò sì rí oúnjẹ.
12 Ṣùgbọ́n nígbà tí Jákọ́bù gbọ́ pé Àlìkámà ń bẹ ni Íjíbítì, ó rán àwọn baba wa lọ lẹ́ẹ̀kínní.
13 Nígbà kejì Jósẹ́fù fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn arákùnrin rẹ̀, a sì tún fi wọ́n hàn fún Fáráò.