26 Ańgẹ́lì Olúwa sì sọ fún Fílípì pé, “Dìde kí ó sì máa lọ sí ìhà gúsù, sí ọ̀nà ijù, tí ó ti Jerúsálémù lọ sí Gásà.”
27 Nígbà tí ó sì dìde, ó lọ; sí kíyèsí, ọkùnrin kan ará Etiópíà, ìwẹ̀fà ọlọ́lá púpọ̀ lọdọ̀ Káńdákè ọba-bìnrin àwọn ara Etiópíà, ẹni tí í se olórí ìsúra rẹ̀, tí ó sì ti wá sí Jerúsálémù láti jọ́sìn,
28 Òun sì ń padà lọ, ó sì jókòó nínú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó ń ka ìwé wòlíì Àìṣáyà.
29 Ẹ̀mí sì wí fún Fílípì pé, “Lọ kí ó si da ara rẹ pọ̀ mọ́ kẹ̀kẹ́ yìí.”
30 Fílípì si súré lọ, ó gbọ́ ti ó ń ka ìwé wòlíì Àìṣáyà, Fílípì sì bí i pé, “Ohun tí ìwọ ń kà yìí ha yé ọ bí?”
31 Ó sì dáhùn wí pé, “Yóò ha ṣe yé mi, bí kò ṣe pé ẹnìkan tọ́ mí sí ọ̀nà?” Ó sì bẹ Fílípì kí ó gòkè wá, kí ó sì bá òun jókòó.
32 Ibi-ìwé-mímọ́ tí Ìwẹ̀fà náà ń kà náà ni èyí:“A fà á bí àgùntàn lọ fún pípa;àti bí ọ̀dọ́-àgùntàn tí ń dákẹ́ níwájú olúrẹ́run rẹ̀,bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kò wí ohun kan.