29 Ẹ̀mí sì wí fún Fílípì pé, “Lọ kí ó si da ara rẹ pọ̀ mọ́ kẹ̀kẹ́ yìí.”
30 Fílípì si súré lọ, ó gbọ́ ti ó ń ka ìwé wòlíì Àìṣáyà, Fílípì sì bí i pé, “Ohun tí ìwọ ń kà yìí ha yé ọ bí?”
31 Ó sì dáhùn wí pé, “Yóò ha ṣe yé mi, bí kò ṣe pé ẹnìkan tọ́ mí sí ọ̀nà?” Ó sì bẹ Fílípì kí ó gòkè wá, kí ó sì bá òun jókòó.
32 Ibi-ìwé-mímọ́ tí Ìwẹ̀fà náà ń kà náà ni èyí:“A fà á bí àgùntàn lọ fún pípa;àti bí ọ̀dọ́-àgùntàn tí ń dákẹ́ níwájú olúrẹ́run rẹ̀,bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kò wí ohun kan.
33 Nínú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ a fi ìdájọ́-ododo dùn ún:Ta ni ó le sọ̀rọ̀ nípa ti àwọn ìran rẹ̀?Nítorí tí a gba ẹ̀mí rẹ̀ kúrò ní ayé.”
34 Ìwẹ̀fà náà sì sọ fún Fílípì pé, “Mo bẹ̀ ọ́ sọ fún mi, nípa ta ni wòlíì náà ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, nípa ara rẹ̀ tàbí nípa ẹlòmìíràn?”
35 Fílípì sí ya ẹnu rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ láti ibi ìwé-mímọ́ yìí, ó sí wàásù ìyìn rere ti Jésù fún un.