11 Ó ń wí pé, “Èyí tí ó wí pé, kọ̀wé rẹ̀, ohun tí ìwọ rí, kí ó sí fi ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ méje; sí Éfésù, àti sí Simirínà, àti sí Párágámù, àti sí Tíátírà, àti sí Sarádì, àti sí Filadéfíà, àti sí Laódíkéà.”
12 Mo sì yí padà láti wo ohùn tí ń bá mi sọ̀rọ̀. Nígbà tí mo yípadà, mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà méje;
13 Àti láàrin àwọn ọ̀pá fìtílà náà, ẹnìkan tí ó dà bí “ọmọ ènìyàn,” tí a wọ̀ ní aṣọ tí ó kanlẹ̀ dé ẹṣẹ̀, tí a sì fi àmùrè wúrà dì ní ẹ̀gbẹ́.
14 Orí rẹ̀ àti irun rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú, ó funfun bí Sínóò; ojú rẹ̀ sì dàbí, ọwọ́ iná;
15 Ẹṣẹ̀ rẹ̀ sì dàbí idẹ dáradára, bí ẹni pé a dà á nínú ìléru; ohùn rẹ̀ sì dàbí ìró omi púpọ̀.
16 Ó sì ní ìràwọ̀ méje ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; àti láti ẹnu rẹ̀ wá ni idà olójú méjì mímú ti jáde: Ojú rẹ̀ sì dàbí òòrùn tí ó ń fi agbára rẹ̀ hàn.
17 Nígbà tí mo rí i, mo wólẹ̀ ní ẹṣẹ̀ rẹ̀ bí ẹni tí ó kú. Ó si fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi, ó ń wí fún mi pé, “Máṣe bẹ̀rù. Èmi ni ẹni-ìṣájú àti ẹni-ìkẹyìn.