1 Mó sì rí ańgẹ́lì mìíràn alágbára ò ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, a fi awọsànmà wọ̀ ọ́ ni aṣọ; òṣùmàrè sì ń bẹ ní orí rẹ̀, ojú rẹ̀ sì dàbí òòrùn, àti ẹṣẹ̀ rẹ̀ bí ọ̀wọ́n iná.
2 Ó sì ní ìwé kékeré kan tí a sí ní owọ́ rẹ̀; ó sì fi ẹṣẹ rẹ̀ ọ̀tún lé òkun, àti ẹṣẹ̀ rẹ̀ òsì lé ilẹ̀.
3 Ó sì ké lóhùn rara, bí ìgbà tí kìnnìún bá bú ramúramù. Nígbà tí ó sì ké, àwọn àrá méje náà fọhùn.
4 Nígbà tí àwọn àrá méje fọhùn, mo múra àti kọ̀wé: mo sì gbọ ohùn láti ọ̀run wá ń wí fún pé, “Fi èdìdì di ohun tí àwọn àrá méje náà sọ, má sì ṣe kọ wọ́n sílẹ̀.”
5 Ańgẹ́lì náà tí mo rí tí ó dúró lórí òkun àti lórí ilẹ̀, sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sí òkè ọ̀run:
6 Ó sì fi ẹni tí ń bẹ láàyè láé àti láé láé búra, ẹni tí o dá ọ̀run, àti ohun tí ń bẹ nínú rẹ̀, pé, “Kí a má ṣe jáfara mọ́.
7 Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ ohùn ìpè ańgẹ́lì kéje, nígbà tí yóò ba fún ìpè, nígbà náà ni ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí o tí sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn wòlíì ni a ó mú ṣẹ.”