12 Wọn sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti ọ̀run wá ń wí fún wọn pé, “Ẹ gòkè wá ìhín!” Wọn sì gòkè lọ sí ọ̀run nínú ìkúukúù àwọsánmà; lójú àwọn ọ̀ta wọn.
13 Ní wákàtí náà ìmìmì-ilẹ̀ ńlá kan sì mì, ìdámẹ̀wàá ìlú náà sì wó, àti nínú ìmìmì-ilẹ̀ náà ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin ènìyàn ní a pa; ẹ̀rù sì ba àwọn ìyókù, wọn sì fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run.
14 Ègbé kéjì kọjá; sì kìyèsí i, ègbé kẹta sì ń bọ̀ wá kánkán.
15 Ańgẹ́lì kéje sì fọn ìpè; a sì gbọ́ ohùn ńlá láti ọ̀run, wí pé,“Ìjọba ayé di ti Olúwa wá, àti tí Kírísítì rẹ̀;òun yóò sì jọba láé àti láéláé!”
16 Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà tí wọn jókòó níwájú Ọlọ́run lórí ìtẹ́ wọn, dojúbolẹ̀, wọn sì sin Ọlọ́run,
17 Wí pé:“Àwa fí ọpẹ́ fún ọ, Olúwa Ọlọ́run, Olódùmarè,tí ń bẹ, tí ó sì ti wà,nítorí pé ìwọ ti gba agbára ńlá rẹ̀,ìwọ sì ti jọba.
18 Inú bí àwọn orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ni ìbínú rẹ̀ ti dé,àti àkókò láti dá àwọn òkú lẹ́jọ́,àti láti fi èrè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì,àti àwọn ènìyàn mímọ́, àti àwọn tí o bẹ̀rù orúkọ rẹ̀,àti ẹni kékeré àti ẹni ńlá;àti láti run àwọn tí ń pa ayé run.”