1 Mo sì rí àmì mìíràn ní ọ̀run tí ó tóbi tí ó sì ya ni lẹ́nu, àwọn ańgẹ́lì méje tí ó ni àwọn ìyọnu méje ìkẹ́yìn, nítorí nínú wọn ni ìbínú Ọlọ́run dé òpin.
2 Mo sì rí bí ẹni pé, òkun dígí tí o dàpọ̀ pẹ̀lú iná: àwọn tí ó sì dúró lórí òkun dígí yìí jẹ́ àwọn ti wọ́n sẹ́gun ẹranko náà, àti àwòrán rẹ̀, àti àmì rẹ̀ àti nọ́ḿba orúkọ rẹ̀, wọn ní Haàpù Ọlọ́run.
3 Wọ́n sì ń kọ orin ti Móṣè, ìránṣẹ́ Ọlọ́run, àti orin ti Ọ̀dọ́-Àgùntàn, wí pé:“Títóbi àti ìyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ,Olúwa Ọlọ́run Olodùmarè;òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀nà rẹ̀,ìwọ Ọba àwọn orílẹ̀-èdè.
4 Ta ni kì yóò bẹ̀rù, Olúwa,tí kì yóò sì fi ògo fún orúkọ rẹ̀?Nítorí ìwọ níkanṣoṣo ni mímọ́.Gbogbo àwọn orílẹ èdè mi yóò sì wá,ti yóò sì foribalẹ̀ níwájú rẹ,nítorí a ti fi ìdájọ́ rẹ hàn.”
5 Lẹ́yìn náà mo sì wo, sì kíyèsí i, a sí tẹ́ḿpìlì àgọ́ ẹ̀rí ní ọ̀run sílẹ̀;
6 Àwọn ańgẹ́lì méje náà sì ti inú tẹ́ḿpìlì jáde wá, wọ́n ni ìyọnu méje náà, a wọ̀ wọ́n ní aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun ti ń dán, a sì fi àmùrè wúrà dì wọ́n ni oókan àyà.
7 Àti ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà fi àgbàda wúrà méje fún àwọn ańgẹ́lì méje náà, tí ó kún fún ìbínú Ọlọ́run, ẹni tí ń bẹ láàyè láé àti láéláé.