5 Lẹ́yìn náà mo sì wo, sì kíyèsí i, a sí tẹ́ḿpìlì àgọ́ ẹ̀rí ní ọ̀run sílẹ̀;
6 Àwọn ańgẹ́lì méje náà sì ti inú tẹ́ḿpìlì jáde wá, wọ́n ni ìyọnu méje náà, a wọ̀ wọ́n ní aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun ti ń dán, a sì fi àmùrè wúrà dì wọ́n ni oókan àyà.
7 Àti ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà fi àgbàda wúrà méje fún àwọn ańgẹ́lì méje náà, tí ó kún fún ìbínú Ọlọ́run, ẹni tí ń bẹ láàyè láé àti láéláé.
8 Tẹ́ḿpìlì náà sì kún fún èéfín láti inú ògo Ọlọ́run àti agbára rẹ̀ wá; ẹnikẹ́ni kò sì lè wọ inú tẹ́ḿpìlì náà lọ títí a fi mú ìyọnu méjèèje àwọn ańgẹ́lì méje náà ṣẹ.