Ìfihàn 18:16-22 BMY

16 Wí pé:“ ‘Ẹ̀gbẹ́! Ẹ̀gbé, ni fún ìlú ńlá nì,tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́,àti ti elése àlùkò, àti ti òdòdó, àti ti a sì fi wúrà ṣe lọ́sọ̀ọ́, pẹ̀lú òkúta iyebíye àti pẹrílì!

17 Nítorí pé ní wákàtí kan ni ọrọ̀ ti o pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ di asán!’“Àti olúkulùkù ẹni tí ń rin ojú omi lọ sí ìbikíbí, àti àwọn ti ń ṣiṣẹ́ nínú ọkọ àwọn ti ń ṣòwò ojú òkun dúró ní òkèrè réré,

18 Wọ́n sì kígbe nígbà tí wọ́n rí èéfín jíjóná rẹ́, wí pé, ‘Ìlú wo ni o dàbí ìlú yìí?’

19 Wọ́n sì kú ekuru sí orí wọn, wọ́n kígbe, wọ́n sọkún, wọn sì ń ṣọ̀fọ̀, wí pé:“ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà,nínú èyí tí a sọ gbogbo àwọn tí ó ni ọkọ̀ní òkun di ọlọ́rọ̀ nípa ohun iyebíye rẹ̀!Nítorí pé ni wákàtí kan, a sọ ọ́ di ahoro.

20 Yọ̀ lórí rẹ̀, ìwọ ọ̀run!Àti ẹ̀yin Àpósítélì mímọ́ àti wòlíì!Nítorí Ọlọ́run ti gbẹ̀san yín lára rẹ̀.’ ”

21 Ańgẹ́lì alágbára kan sì gbé òkúta kan sókè, ó dàbí ọlọ ńlá, ó sì jù ú sínú òkun, wí pé:“Báyìí ní a ó fi agbára ńlábíi Bábílónì ìlú ńlá ni wó,a kì yóò sì rí i mọ́ láé.

22 Àti ohùn àwọn aludùùrù, àti ti àwọn olórin,àti ti àwọn afọnrèrè, àti ti àwọn afọ̀npè,ni a kì yóò sì gbọ́ nínú rẹ mọ́ rara;àti olukulùkù oníṣọ̀nà ohunkóhun ni a kì yóò sì rí nínú rẹ mọ́ láé:Àti ìró ọlọ ní a kì yóòsì gbọ́ mọ̀ nínú rẹ láé;