Ìfihàn 18:6-12 BMY

6 San an fún un, àní bí òun tí san án fún ní,kí ó sì ṣe e ni ìlọ́po méjì fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀Nínú ago náà tí o ti kún, òun ni kí ẹ sì kún fún un ni méjì.

7 Níwọ̀n bí o ti yin ara rẹ̀ lógo tó,tí ó sì hùwà wọ̀bìà,níwọ̀n bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ dá a lóró kí ẹ sì fún un ní ìbànújẹ́;nítorí tí ó wí ní ọkàn rẹ̀ pé,‘Mo jókòó bí ọbabìnrin,èmi kì sì í ṣe opó, èmí kì yóò sì rí ìbànújẹ́ láé.’

8 Nítorí náà, ní ìjọ kan ni ìyọnu rẹ̀ yóò dé,ìkú, àti ìbìnújẹ́, àti ìyàn;a ó sì fi iná sun ún pátapáta:nítorí pé alágbára ni Olúwa Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀.

9 “Àti àwọn ọba ayé, tí ó ti ń bá a ṣe àgbérè, ti wọn sì ń hùwà wọ̀bìà, yóò sì pohùnréré ẹkún lé e lórí, nígbà tí wọn bá wo èéfín ìjóná rẹ̀.

10 Wọ́n ó dúró ní òkèrè réré nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ́ oró rẹ̀, wọn ó máa wí pé:“ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà,Bábílónì ìlú alágbára nì!Nítorí ní wákàtí kan ni ìdájọ́ rẹ dé!’

11 “Àwọn oníṣòwò ayé sì ń sọkún, wọn sì ń sọ̀fọ̀ lórí rẹ̀, nítorí pé ẹnikẹ́ni kò rà ọjà wọn mọ́:

12 Ọjà wúrà, àti ti fàdákà, àti ti òkúta iyebíye, àti ti pẹ́rílì, àti ti aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, àti tí elése àlùkò, àti ti sẹ́dà, àti ti òdòdó, àti ti gbogbo igi olóòórùn dídùn, àti ti olúkúlùkù ohun èlò tí a fi igi iyebíye ṣe, àti ti idẹ, àti ti irin, àti ti òkúta mabílì.