3 Àti lẹ́ẹ̀kejì wọ́n wí pé:“Halelúyà!Èéfín rẹ̀ sì gòkè lọ láé àti láéláé.”
4 Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún nì, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin nì sì wólẹ, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wí pé:“Àmín, Halelúyà!”
5 Ohùn kan sì ti ibi ìtẹ́ náà jáde wá, wí pé:“Ẹ máa yin Ọlọ́run wa,ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo,ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù rẹ̀,àti èwe àti àgbà!”
6 Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àti bí ìró omi púpọ̀, àti bí ìró àrá ńláńlá, ń wí pé:“Halelúyà!Nítorí Olúwa Ọlọ́run wa, Olódùmarè ń jọba.
7 Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí inú wa kí ó sì dùn gidigidi,kí a sì fi ògo fún un.Nítorí pé ìgbéyàwó Ọ̀dọ́-Àgùntàn dé,aya rẹ̀ sì ti múra tán.
8 Òun ni a sì fi fún pé kí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀wíwẹ́ tí ó funfun gbòò.”(Nítorí pé aṣọ ọ̀gbọ̀ nì dúró fún iṣẹ́ òdodo àwọn ènìyàn mímọ́.)
9 Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, ‘Ìbùkún ni fún àwọn tí a pè sí àsè-alẹ́ ìgbéyàwó ọ̀dọ́-àgùntàn.’ ” Ó sì wí fún mi pé: “Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run.”