Ìfihàn 19:4-10 BMY

4 Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún nì, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin nì sì wólẹ, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wí pé:“Àmín, Halelúyà!”

5 Ohùn kan sì ti ibi ìtẹ́ náà jáde wá, wí pé:“Ẹ máa yin Ọlọ́run wa,ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo,ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù rẹ̀,àti èwe àti àgbà!”

6 Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àti bí ìró omi púpọ̀, àti bí ìró àrá ńláńlá, ń wí pé:“Halelúyà!Nítorí Olúwa Ọlọ́run wa, Olódùmarè ń jọba.

7 Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí inú wa kí ó sì dùn gidigidi,kí a sì fi ògo fún un.Nítorí pé ìgbéyàwó Ọ̀dọ́-Àgùntàn dé,aya rẹ̀ sì ti múra tán.

8 Òun ni a sì fi fún pé kí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀wíwẹ́ tí ó funfun gbòò.”(Nítorí pé aṣọ ọ̀gbọ̀ nì dúró fún iṣẹ́ òdodo àwọn ènìyàn mímọ́.)

9 Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, ‘Ìbùkún ni fún àwọn tí a pè sí àsè-alẹ́ ìgbéyàwó ọ̀dọ́-àgùntàn.’ ” Ó sì wí fún mi pé: “Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run.”

10 Mo sì wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ láti foríbalẹ̀ fún un. Ó sì wí fún mi pé, “Wò ó, má ṣe bẹ́ẹ̀: ìránṣẹ́ ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n di ẹ̀rí Jésù mú: foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run: nítorí pé ẹ̀rí Jésù ni ìsọtẹ́lẹ̀.”