Ìfihàn 2:17-23 BMY

17 Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ; Ẹni tí o bá ṣẹ́gun ni èmi o fi mánà tí ó pamọ́ fún, èmi ó sì fún un ni òkúta funfun kan, àti sára òkúta náà ni a kọ orúkọ tuntun kan, tí ẹnìkan kò mọ̀ bí kò ṣe ẹni tí ó gbà á.

18 “Àti sí Ańgẹ́lì ìjọ ní Tíátírà kọ̀wé:Nǹkan wọ̀nyí ni Ọmọ Ọlọ́run wí, ẹni tí ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́ iná, tí ẹṣẹ̀ rẹ̀ sì dàbí idẹ dáradára:

19 Èmi mọ̀ iṣẹ́, ìfẹ́, àti ìgbàgbọ́ àti ìsìn àti sùúrù rẹ̀; àti pé iṣẹ́ rẹ̀ ìkẹyìn ju tí iṣàájú lọ.

20 Ṣùgbọ́n èyí ni mo rí wí sì ọ: Nítorí tí ìwọ fi àyè sílẹ̀ fún obìnrin Jésébẹ́lì tí ó ń pe ara rẹ̀ ní wòlíì. Nípaṣ ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó sì ń kọ́ àwọn ìránṣẹ́ mi, ó sì ń tàn wọ́n láti máa ṣe àgbèrè, àti láti máa jẹ ohun tí a pa rúbọ sì òrìṣà.

21 Èmi fi àkókò fún un, láti ronúpìwàdà; ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ ronúpìwàdà àgbèrè rẹ̀.

22 Nítorí náà, èmi ó gbé e sọ sí orí àkéte, àti àwọn tí ń bá a ṣe panṣágà ni èmi ó fi sínú ìpọ́njú ńlá, bí kò ṣe bí wọ́n bá ronúpìwàdà iṣẹ́ wọn.

23 Èmi o pa àwọn ọmọ rẹ̀; gbogbo ìjọ ni yóò sì mọ̀ pé, èmi ni ẹni tí ń wádìí inú àti ọkàn: èmi ó sì fi fún olúkúlùkù yín gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.