21 Èmi fi àkókò fún un, láti ronúpìwàdà; ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ ronúpìwàdà àgbèrè rẹ̀.
22 Nítorí náà, èmi ó gbé e sọ sí orí àkéte, àti àwọn tí ń bá a ṣe panṣágà ni èmi ó fi sínú ìpọ́njú ńlá, bí kò ṣe bí wọ́n bá ronúpìwàdà iṣẹ́ wọn.
23 Èmi o pa àwọn ọmọ rẹ̀; gbogbo ìjọ ni yóò sì mọ̀ pé, èmi ni ẹni tí ń wádìí inú àti ọkàn: èmi ó sì fi fún olúkúlùkù yín gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.
24 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni mò ń sọ fún, ẹ̀yin ìyókù tí ń bẹ ní Tíátírà, gbogbo ẹ̀yin tí kò ni ẹ̀kọ́ yìí, ti kò ì tí ì mọ̀ ohun tí wọn pe ni ohun ìjìnlẹ̀ Sàtánì, èmi kò di ẹrù mìíràn rù yín:
25 Ṣùgbọ́n èyí tí ẹ̀yin ní, ẹ di i mú ṣinṣin títí èmi ó fi dé.
26 Ẹni tí ó bá sì ṣẹ́gun, àti tí o sì ṣe ìfẹ́ mi títí dé òpin, èmi o fún un láṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè:
27 ‘Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn;gẹ́gẹ́ bí a ti ń fọ́ ohun-èlò amọ̀kòkò ni a ó fọ́ wọn túútúú,’gẹ́gẹ́ bí èmi pẹ̀lú tí gbà àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Baba mi.