4 A sì fún wọn pé ki wọn má ṣe pa koríko ilẹ̀ lára tàbí ohun tútù kan, tàbí igikígi kan; bí kò ṣe àwọn ènìyàn tí kò ni èdìdì Ọlọ́run ní iwájú wọn.
5 A sì pàṣẹ fún wọn pé, kí wọn má ṣe pa wọ́n, ṣùgbọ́n kí a dá wọn ni oró ni oṣù marùn-ún: oró wọn sì dàbí oró àkéekèe, nígbà tí o bá ta ènìyàn.
6 Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn yóò sì máa wá ikú, wọn kì yóò sì rí i; wọn yóò sì fẹ́ láti kú, ikú yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ wọn.
7 Ìrísí àwọn eṣú náà sì dàbí àwọn ẹṣin tí a múra sílẹ̀ fún ogun; àti ní orí wọn ni ohun tí o dàbí àwọn adé wúrà wà, ojú wọn sì dàbí ojú ènìyàn;
8 Wọn sì ní irun bí obìnrin, ehín wọn sì dàbí ti kìnìún.
9 Wọn sì ní ìgbàyà tí ó dàbí ìgbàyà irin; ìró ìyẹ́ wọn sì dàbí ìró kẹ̀kẹ́ ẹsin púpọ̀ tí ń súré lọ sí ogun.
10 Wọ́n sì ni ìrù àti oró bí tí àkéekèe, àti ní ìrù wọn ni agbára wọn wà láti pa ènìyàn lára fún oṣù márùn-ún.